Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Saamu 142

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Èmi kígbe sókè sí Olúwa; èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú.
2Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.
3Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi, ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi. Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀.
4Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi èmi kò ní ààbò; kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi.
5Èmi kígbe sí ọ, Olúwa: èmi wí pé, “Ìwọ ni ààbò mi, ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”
6Fi etí sí igbe mi, nítorí tí èmi wà nínú àìnírètí gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi, nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ.
7Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú, kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ. Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkiri nítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.