Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Saamu 141

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Olúwa, èmi ké pè ọ́; yára wá sí ọ̀dọ̀ mi. Gbọ́ ohùn mi, nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.
2Jẹ́ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú rẹ bí ẹbọ tùràrí àti ìgbé ọwọ́ mi si òkè rí bí ẹbọ àṣálẹ́.
3Fi ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ẹnu mi, Olúwa: kí o sì máa pa ìlẹ̀kùn ètè mi mọ́.
4Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun tí ń ṣe ibi, láti máa bá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ búburú má sì ṣe jẹ́ kí èmi jẹ àdídùn wọn.
5Jẹ́ kí olódodo lù mí, ìṣeun ni ó jẹ́: jẹ́ kí ó bá mi wí, ó jẹ́ òróró ní orí mi. Tí kì yóò fọ́ mi ní orí. Síbẹ̀ àdúrà mi wá láìsí ìṣe àwọn olùṣe búburú.
6A ó ju àwọn alákòóso sílẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ òkúta, àwọn ẹni búburú yóò kọ pé àwọn ọ̀rọ̀ mi dùn.
7Wọn yóò wí pé, “Bí ẹni tí ó la aporo sórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni egungun wa tànkálẹ̀ ní ẹnu isà òkú.”
8Ṣùgbọ́n ojú mi ń bẹ lára rẹ, Olúwa Olódùmarè; nínú rẹ̀ ni èmi ti rí ààbò, má ṣe fà mi fún ikú.
9Pa mí mọ́ kúrò nínú okùn tí wọn ti dẹ sílẹ̀ fún mi, kúrò nínú ìkẹ́kùn àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
10Jẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣubú sínú àwọ̀n ara wọn, nígbà tí èmi bá kọjá lọ láìléwu.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.