Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Orin Solomoni 7

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Báwo ni ẹsẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà. Ìwọ ọmọbìnrin ọba! Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́ iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà
2Ìdodo rẹ rí bí àwo tí kì í ṣe aláìní ọtí, ìbàdí rẹ bí òkìtì alikama tí a fi lílì yíká.
3Ọmú rẹ rí bí abo egbin méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín.
4Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín erin. Ojú rẹ rí bí adágún ní Heṣboni ní ẹ̀bá ẹnu ibodè Bati-Rabbimu. Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lebanoni tí ó kọ ojú sí Damasku.
5Bí òkè Karmeli ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká, bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ ká a fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn.
6Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tó báwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́?
7Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ, àti ọmú rẹ bí ìdì èso àjàrà.
8Mo ní, “Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ, èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú.” Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà, àti èémí imú rẹ bí i ápù.
9Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ. Tí ó kúnná tí ó sì dùn, tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀.
10Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe, èmi sì ni ẹni tí ó wù ú.
11Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá, jẹ́ kí a lo àṣálẹ́ ní àwọn ìletò.
12Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtù láti wo bí àjàrà rúwé bí ìtànná àjàrà bá là. Àti bí pomegiranate bá ti rudi, níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.
13Àwọn èso mándrákì mú òórùn wọn jáde ní ẹnu-ọ̀nà wa ni onírúurú àṣàyàn èso, èso tuntun àti ọjọ́ pípẹ́ tí mo ti kó pamọ́ fún ọ, olùfẹ́ mi.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.