Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Saamu 92

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,
2láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́,
3lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá àti lára ohun èlò orin haapu.
4Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa; èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
5Báwo ni iṣẹ́ rẹ tí tóbi tó, Olúwa? Èrò inú rẹ ìjìnlẹ̀ ni!
6Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n, aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n,
7nígbà tí àwọn ènìyàn búburú bá rú jáde bí i koríko àti gbogbo àwọn olùṣe búburú gbèrú, wọn yóò run láéláé.
8Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.
9Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ, Olúwa, nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé; gbogbo àwọn olùṣe búburú ni a ó fọ́nká.
10Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó; òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.
11Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi; ìparun sí àwọn ènìyàn búburú tí ó dìde sí mi.
12Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ, wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni,
13tí a gbìn sí ilé Olúwa, Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
14Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó, wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,
15láti fihàn pé, “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa; òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú kankan nínú rẹ̀.”
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.