Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Saamu 90

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.
2Kí a tó bí àwọn òkè ńlá àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé, láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.
3Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀, wí pé, “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.”
4Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún bá kọjá lójú rẹ, bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
5Ìwọ gbá ènìyàn dànù nínú oorun ikú; wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
6Lóòtítọ́, ní òwúrọ̀, ó yọ tuntun ní àṣálẹ́ ni yóò gbẹ, tí yóò sì rẹ̀ dànù.
7A pa wá run nípa ìbínú rẹ nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá.
8Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú rẹ, àti ohun ìkọ̀kọ̀ wa nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ.
9Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú rẹ; àwa ń lo ọjọ́ wa lọ bí àlá tí à ń rọ́.
10Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá, bi ó sì ṣe pé nípa agbára tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún, agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni, nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò, àwa a sì fò lọ.
11Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ? Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ.
12Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára, kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.
13Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ tó? Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ.
14Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ, kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀ kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.
15Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú, fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.
16Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.
17Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa; fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa, bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.