Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Saamu 80

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli; ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran. Ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù, tàn jáde
2níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase. Ru agbára rẹ̀ sókè; wá fún ìgbàlà wa.
3Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run; jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí a bá à lè gbà wá là.
4Olúwa Ọlọ́run alágbára, ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?
5Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
6Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa, àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.
7Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára; jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa, kí a ba à lè gbà wá là.
8Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti; ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín.
9Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un, ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀ ó sì kún ilẹ̀ náà.
10A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀, ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run.
11O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun, ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì.
12Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀ tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀?
13Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́ àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.
14Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára! Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó! Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,
15gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn, àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ.
16A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún; ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé.
17Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ.
18Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ; mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.
19Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára; kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí á ba à lè gbà wá là.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.