Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Saamu 66

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ilẹ̀ gbogbo!
2Ẹ kọrin ọlá orúkọ rẹ̀; ẹ kọrin ìyìnsí i.
3Ẹ wí fún Ọlọ́run pé, “Ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ rẹ! Nípa ọ̀pọ̀ agbára rẹ ni àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi sìn ọ́.
4Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ; wọn ń kọrin ìyìn sí ọ, wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Sela.
5Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe, iṣẹ́ rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!
6Ó yí òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ, wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá, níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀.
7Ó ń jẹ ọba títí láé nípa agbára rẹ̀, ojú rẹ̀ ń wo orílẹ̀-èdè kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela.
8Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn, jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀;
9Ó ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa, kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí ó yẹ̀.
10Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò; ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò.
11Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa.
12Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí àwa la iná àti omi kọjá ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.
13Èmi ó wá sí tẹmpili rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ,
14ẹ̀jẹ́ tí ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọ nígbà tí mo wà nínú ìṣòro.
15Èmi ó rú ẹbọ sísun ọlọ́ràá sí ọ, àti ẹbọ ọ̀rá àgbò; èmi ó rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. Sela.
16Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run; ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi.
17Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i, ìyìn rẹ̀ wà ní ẹnu mi.
18Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi, Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi;
19ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́ ó ti gbọ́ ohùn mi nínú àdúrà.
20Ìyìn ni fún Ọlọ́run ẹni tí kò kọ àdúrà mi tàbí mú ìfẹ́ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.