Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Saamu 62

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi; ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.
2Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.
3Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó? Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á, bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ?
4Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú kúrò nínú ọlá rẹ̀; inú wọn dùn sí irọ́. Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. Sela.
5Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi. Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.
6Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò.
7Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run; Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.
8Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn; tú ọkàn rẹ jáde sí i, nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.
9Nítòótọ́, asán ni àwọn ọmọ ènìyàn, èké sì ni àwọn olóyè, wọ́n gòkè nínú ìwọ̀n, lápapọ̀ wọ́n jẹ́ èémí.
10Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára, tàbí gbéraga nínú olè jíjà, nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i, má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn.
11Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mo gbọ́ èyí pé, “Ti Ọlọ́run ni agbára,
12pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa, tìrẹ ni àánú; nítorí tí ìwọ san án fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.”
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.