Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Saamu 6

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ.
2Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń kú lọ; Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.
3Ọkàn mi wà nínú ìrora. Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó?
4Yípadà, Olúwa, kí o sì gbà mí; gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í.
5Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú. Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú?
6Agara ìkérora mi dá mi tán. Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún, mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.
7Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́; wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.
8Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi, nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.
9Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú; Olúwa ti gba àdúrà mi.
10Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú; wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.