Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Saamu 59

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi, Ọlọ́run; dáàbò bò mí kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó dìde sí mi.
2Gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ búburú kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń pòǹgbẹ ẹ̀jẹ̀.
3Wò ó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí! Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí mi kì í ṣe nítorí ìrékọjá mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, Olúwa.
4Èmi kò ṣe àìṣedéédéé kan, síbẹ̀ wọ́n sáré wọ́n ṣetán láti kọlù mí. Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi, kí o sì wo àìlera mi.
5Olúwa Ọlọ́run Alágbára, Ọlọ́run Israẹli, dìde fún ara rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀-èdè wí; má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì. Sela.
6Wọ́n padà ní àṣálẹ́, wọ́n ń gbó bí àwọn ajá, wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri.
7Kíyèsi ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu: wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn, wọ́n sì wí pé, “Ta ni ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?”
8Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, yóò fi wọ́n rẹ́rìn-ín, Ìwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.
9Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ; nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi,
10Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi. Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi. Yóò sì jẹ́ kí n yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi.
11Ṣùgbọ́n má ṣe pa wọ́n, Olúwa asà wa, kí àwọn ènìyàn mi má ba à gbàgbé. Nínú agbára rẹ, jẹ́ kí wọn máa rìn kiri, kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
12Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn, ní ọ̀rọ̀ ètè wọn, kí a mú wọn nínú ìgbéraga wọn. Nítorí èébú àti èké tí wọn ń sọ,
13pa wọ́n run nínú ìbínú, run wọ́n di ìgbà tí wọn kò ní sí mọ́. Nígbà náà ni yóò di mí mọ̀ dé òpin ayé pé Ọlọ́run jẹ ọba lórí Jakọbu. Sela.
14Wọ́n padà ní àṣálẹ́, wọn ń gbó bí àwọn ajá wọ́n ń rin ìlú náà káàkiri.
15Wọ́n ń rin kiri fún oúnjẹ wọ́n sì ń yán nígbà tí wọn kò yó.
16Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára rẹ, n ó kọrin ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀; nítorí ìwọ ni ààbò mi, ibi ìsádi mi ní ìgbà ìpọ́njú.
17Ìwọ agbára mi, èmi ó kọrin ìyìn sí ọ; ìwọ, Ọlọ́run, ààbò mi, Ọlọ́run ìfẹ́ mi.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.