Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Saamu 48

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.
2Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀, ayọ̀ gbogbo ayé, òkè Sioni, ní ìhà àríwá ní ìlú ọba ńlá.
3Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀; ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.
4Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀, wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.
5Wọn rí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n, a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ.
6Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀, ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.
7Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi, wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.
8Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa rí, ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ìlú Ọlọ́run wa, Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela.
9Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run, àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
10Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run, ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé, ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.
11Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀ kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn nítorí ìdájọ́ rẹ.
12Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀, ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.
13Kíyèsi odi rẹ̀, kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀ kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.
14Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé, Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.