Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Saamu 39

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Mo wí pé, “Èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀; èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”
2Mo fi ìdákẹ́ ya odi; mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere; ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i.
3Àyà mi gbóná ní inú mi. Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn; nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀:
4“Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi, àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.
5Ìwọ ti ṣe ayé mi bí ìbú àtẹ́lẹwọ́, ọjọ́ orí mi sì dàbí asán ní iwájú rẹ. Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.
6“Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji. Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán; wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ, wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.
7“Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, Olúwa, kín ni mo ń dúró dè? Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.
8Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo. Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn àwọn ènìyàn búburú.
9Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́; èmi kò sì ya ẹnu mi, nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.
10Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi; èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.
11Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀ fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ a mú ẹwà rẹ parun bí kòkòrò aṣọ; nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.
12“Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa, kí o sì fetí sí igbe mi; kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi. Nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ, àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.
13Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára, kí èmi tó lọ kúrò níhìn-ín yìí, àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.