Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Saamu 24

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀, ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;
2nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí òkun ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.
3Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ? Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?
4Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun, ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán tí kò sì búra èké.
5Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa, àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.
6Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.
7Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà; kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé! Kí ọba ògo le è wọlé.
8Ta ni ọba ògo náà? Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le, Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.
9Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà; kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo le è wọlé wá.
10Ta ni Ọba ògo náà? Olúwa àwọn ọmọ-ogun Òun ni Ọba ògo náà. Sela.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.