Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Saamu 14

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé, “Ko sí Ọlọ́run.” Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú; kò sí ẹnìkan tí yóò ṣe rere.
2Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá lórí àwọn ọmọ ènìyàn bóyá ó le rí ẹni tí òye yé, ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.
3Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́; kò sì ṣí ẹni tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.
4Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní ìmọ̀? Àwọn tí ó ń pa ènìyàn mi jẹ bí ẹní jẹun; wọn kò sì ké pe Olúwa?
5Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù, nítorí Ọlọ́run wà ní àwùjọ àwọn olódodo.
6Ẹ̀yin olùṣe búburú da èrò àwọn tálákà rú, ṣùgbọ́n Olúwa ni ààbò wọn.
7Ìgbàlà àwọn Israẹli yóò ti Sioni wá! Nígbà tí Olúwa bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, jẹ́ kí Jakọbu kí ó yọ̀, kí inú Israẹli kí ó dùn!
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.