Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Saamu 132

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Olúwa, rántí Dafidi nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
2Ẹni tí ó ti búra fún Olúwa, tí ó sì ṣe ìlérí fún alágbára Jakọbu pé.
3Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ, bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gun orí àkéte mi.
4Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi, tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,
5títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa, ibùjókòó fún alágbára Jakọbu.
6Kíyèsi i, àwa gbúròó rẹ̀ ni Efrata: àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.
7Àwa ó lọ sínú àgọ́ rẹ̀: àwa ó máa sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀
8Olúwa, dìde sí ibi ìsinmi rẹ: ìwọ, àti àpótí agbára rẹ.
9Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ: kí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.
10Nítorí tí Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀, má ṣe yí ojú ẹni òróró rẹ padà.
11Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi, Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀, nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.
12Bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́ àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn, àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ láéláé.
13Nítorí tí Olúwa ti yan Sioni: ó ti fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀.
14Èyí ni ibi ìsinmi mi láéláé: níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé: nítorí tí mo fẹ́ ẹ.
15Èmi yóò bùkún oúnjẹ rẹ̀ púpọ̀púpọ̀: èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà rẹ̀ lọ́rùn.
16Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ̀: àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀.
17Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwo Dafidi yọ̀, èmi ti ṣe ìlànà fìtílà kan fún ẹni òróró mi.
18Àwọn ọ̀tá rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀: ṣùgbọ́n lára òun tìkára rẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.