Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Saamu 108

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin.
2Jí ohun èlò orin àti haapu! Èmi ó jí ní kùtùkùtù,
3èmi ó yìn ọ́, Olúwa, nínú àwọn orílẹ̀-èdè, èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn.
4Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ ju àwọn ọ̀run lọ àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀.
5Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run, àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé.
6Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là; fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà, kí o sì dá mi lóhùn
7Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀ pé, “Èmi yóò yọ̀, èmi yóò pín Ṣekemu, èmi yóò sì wọn àfonífojì Sukkoti kúrò.
8Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi, Efraimu ni ìbòrí mi, Juda ni olófin mi,
9Moabu sì ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Edomu ni èmi ó bọ́ bàtà mi sí, lórí òkè Filistia ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.”
10Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi? Ta ni yóò sìn mí wá sí Edomu?
11Ìwọ Ọlọ́run ha kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀. Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́.
12Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú, nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni.
13Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin nítorí òun ó tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.