Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Òwe 22

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Yíyan orúkọ rere sàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ, àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ.
2Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọpọ̀: Olúwa ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.
3Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀, ó ṣé ara rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n ní yà.
4Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.
5Ègún àti ìdẹ̀kùn ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà: ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn.
6Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.
7Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú, ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè.
8Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán: ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà.
9Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún; nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú.
10Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde; nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun.
11Ẹni tí ó fẹ́ ìwà funfun ti àyà, tí ó sì ń sọ̀rọ̀ iyì jáde, ọba yóò ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀.
12Ojú Olúwa pa ìmọ̀ mọ́, ó sì yí ọ̀rọ̀ olùrékọjá pò.
13Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde! Yóò pa mí ní ìgboro!”
14Ẹnu àwọn àjèjì obìnrin, ihò jíjìn ni; ẹni tí a ń bínú sí láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá ni yóò ṣubú sínú rẹ̀.
15Àyà ọmọdé ni ìwà wèrè dì sí; ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
16Ẹni tó ń ni tálákà lára láti ní ọrọ̀, tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ, yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí. Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.
17Dẹtí rẹ sílẹ̀, kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n, kí o sì fi àyà rẹ sí ẹ̀kọ́ mi.
18Nítorí ohun dídùn ni bí ìwọ bá pa wọ́n mọ́ ní inú rẹ; nígbà tí a sì pèsè wọn tán ní ètè rẹ.
19Kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lè wà ní ti Olúwa, èmi fihàn ọ́ lónìí, àní fún ọ.
20Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradára sí ọ ní ti ìmọ̀ràn àti ní ti ẹ̀kọ́,
21kí ó lè mú ọ mọ ìdájú ọ̀rọ̀ òtítọ́; kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́ fún àwọn tí ó rán ọ?
22Má ṣe ja tálákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ tálákà: bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè,
23nítorí Olúwa yóò gbèjà wọn, yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà.
24Má ṣe bá oníbìínú ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́; má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn.
25Kí ìwọ má ba à kọ́ ìwà rẹ̀, ìwọ a sì gba ìkẹ́kùn fún ara rẹ.
26Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀nwọ́, tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè.
27Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi san, nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹni rẹ kúrò lábẹ́ rẹ?
28Má ṣe yẹ ààlà ilẹ̀ ìgbàanì, tí àwọn baba rẹ ti pa.
29Ìwọ ha rí ènìyàn tí ó ń fi àìṣe ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀? Òun yóò dúró níwájú àwọn ọba; òun kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn lásán.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.