Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Òwe 20

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọtí líle; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi tànjẹ kò gbọ́n.
2Ìbẹ̀rù ọba dàbí kíké e kìnnìún; ẹnikẹ́ni tí ó bá mú un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́.
3Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà, ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.
4Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ, nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.
5Ète ọkàn ènìyàn dàbí omi jíjìn; ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde.
6Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń sọ pe àwọn ní ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn, ṣùgbọ́n kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòtítọ́.
7Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkù ìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.
8Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ yóò fẹ́ gbogbo ibi dànù pẹ̀lú ojú rẹ̀.
9Ta ni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́, mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?
10Ìwọ̀n èké àti òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ Olúwa kórìíra méjèèjì.
11Kódà a mọ ọmọdé nípa iṣẹ́ rẹ̀ nípa pe bóyá iṣẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé ó tọ̀nà.
12Etí tí ó ń gbọ́ àti ojú tí ó ń ríran Olúwa ni ó dá méjèèjì.
13Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di tálákà. Ma ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ.
14“Kò dára, kò dára!” ní ẹni tó ra ọjà máa ń wí; nígbà tí ó bá kúrò níbẹ̀ tán, yóò máa yangàn bí òun tí ṣe rí rà sí.
15Wúrà wà, iyùn sì wà rẹpẹtẹ, ṣùgbọ́n, ahọ́n tí ń sọ ìmọ̀ gan an ni ọ̀ṣọ́ iyebíye.
16Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò; mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn.
17Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà èrú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn, ṣùgbọ́n, a yọrí sí ibi ẹnu tí ó kún fún erùpẹ̀.
18Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀ràn bí o bá ń jagun, gba ìtọ́sọ́nà.
19Olófòófó a máa tú àṣírí nítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ púpọ̀.
20Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri.
21Ogún tí a kójọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín.
22Má ṣe wí pé, “N ó sẹ̀san àṣìṣe rẹ yìí fún ọ.” Dúró de Olúwa yóò sì gbà ọ́ là.
23Olúwa kórìíra òdínwọ̀n èké. Òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.
24Olúwa ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyàn. Báwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni?
25Ìdẹ̀kùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíá nígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò.
26Ọlọ́gbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká; Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n.
27Àtùpà Olúwa ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàn a máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú.
28Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́, nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu.
29Ògo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ni agbára wọn, ewú orí ni iyì arúgbó.
30Ìgbájú ìgbámú àti ìfarapa máa ń mú ibi lọ, pàṣán sì máa ń ṣe àfọ̀mọ́ ibi ìkọ̀kọ̀ inú.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.