Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Ẹkún Jeremiah 5

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Rántí, Olúwa, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa; wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa.
2Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò, ilé wa ti di ti àjèjì.
3Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba, àwọn ìyá wa ti di opó.
4A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu; igi wa di títà fún wa.
5Àwọn tí ó ń lé wa súnmọ́ wa; àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.
6Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Ejibiti àti Asiria láti rí oúnjẹ tó tó jẹ.
7Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣí mọ́, àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
8Àwọn ẹrú ń jẹ ọba lórí wa, kò sì ṣí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn.
9Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wa nítorí idà tí ó wà ní aginjù.
10Ẹran-ara wa gbóná bí ààrò, ebi sì yó wa bí àárẹ̀.
11Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lòpọ̀ ní Sioni, àti àwọn wúńdíá ti o wa ní ìlú Juda.
12Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di síso sókè ní ọwọ́ wọn; kò sí ìbọ̀wọ̀ fún àgbàgbà mọ́.
13Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa ru òkúta; àwọn ọmọkùnrin sì ń ṣàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.
14Àwọn àgbàgbà ti lọ kúrò ní ẹnu-bodè ìlú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn.
15Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa; ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.
16Adé ti ṣí kúrò ní orí wa ègbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀.
17Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa, nítorí èyí, ojú wa sì ṣú.
18Fún òkè Sioni tí ó ti di ahoro lórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri.
19Ìwọ, Olúwa, jẹ ọba títí láé; ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn.
20Kí ló dé tí o ń gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà? Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́?
21Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, Olúwa, kí àwa kí ó le padà; mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbàanì,
22àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátá tí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.