Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Jobu 40

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Olúwa dá Jobu lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wí pé,
2“Ẹni tí ń bá Olódùmarè wíjọ́ yóò ha kọ ní ẹ̀kọ́? Ẹni tí ń bá Ọlọ́run wí jẹ́ kí ó dáhùn!”
3Nígbà náà ni Jobu dá Olúwa lóhùn wá ó sì wí pé,
4“Kíyèsi i, ẹ̀gbin ni èmi—ohun kí ni èmi ó dà? Èmi ó fi ọwọ́ mi le ẹnu mi.
5Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kì yóò tún sọ mọ́; lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì le ṣe é mọ́.”
6Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé,
7“Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin, èmi ó bi ọ léèrè, kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.
8“Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán? Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo.
9Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun?
10Fi ọláńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́, tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bo ara ní aṣọ.
11Mú ìrunú ìbínú rẹ jáde; kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.
12Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀ kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.
13Sin gbogbo wọn papọ̀ nínú erùpẹ̀, kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú.
14Nígbà náà ní èmi ó yìn ọ́ pé, ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.
15“Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti, tí mo dá pẹ̀lú rẹ, òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.
16Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.
17Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀.
18Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ, Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.
19Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run; síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.
20Nítòótọ́ òkè ńlá ńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá, níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀.
21Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì, lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀.
22Igi lótusì síji wọn bò o; igi arọrọ odò yí i káàkiri.
23Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ; ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀.
24Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀, tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.