Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Jobu 38

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé,
2“Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìlóye láti fi ṣókùnkùn bo ìmọ̀ mi?
3Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí, nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ kí o sì dá mi lóhùn.
4“Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye.
5Ta ni ó fi ìwọ̀n rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n? Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ?
6Lórí ibo ni a gbé kan ìpìlẹ̀ rẹ̀ mọ́, tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀,
7nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀?
8“Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi òkun mọ́, nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá.
9Nígbà tí mo fi àwọsánmọ̀ ṣe aṣọ rẹ̀, tí mo sì fi òkùnkùn biribiri ṣe ọ̀já ìgbà inú rẹ̀.
10Nígbà tí mo ti pàṣẹ ìpinnu mi fún un, tí mo sì ṣe bèbè àti ìlẹ̀kùn.
11Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé, kí o má sì rékọjá, níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ?
12“Ìwọ pàṣẹ fún òwúrọ̀ láti ìgbà ọjọ́ rẹ̀ wá, ìwọ sì mú ìlà-oòrùn mọ ipò rẹ̀,
13í ó lè di òpin ilẹ̀ ayé mú, ki a lè gbọ́n àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú rẹ̀?
14Kí ó yí padà bí amọ̀ fún èdìdì amọ̀, kí gbogbo rẹ̀ kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni pé nínú aṣọ ìgúnwà.
15A sì fa ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn búburú, apá gíga ni a sì ṣẹ́.
16“Ìwọ ha wọ inú ìsun òkun lọ rí bí? Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá?
17A ha ṣílẹ̀kùn ikú sílẹ̀ fún ọ rí bí, ìwọ sì rí ìlẹ̀kùn òjìji òkú?
18Ìwọ mòye ìbú ayé bí? Sọ bí ìwọ bá mọ gbogbo èyí.
19“Ọ̀nà wo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé? Bí ó ṣe ti òkùnkùn, níbo ni ipò rẹ̀,
20tí ìwọ í fi mú un lọ sí ibi àlá rẹ̀, tí ìwọ ó sì le mọ ipa ọ̀nà lọ sínú ilé rẹ̀?
21Ìwọ mọ èyí, nítorí nígbà náà ni a bí ọ? Iye ọjọ́ rẹ sì pọ̀.
22“Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì òjò lọ rí bí, ìwọ sì rí ilé ìṣúra yìnyín rí,
23tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu, dé ọjọ́ ogun àti ìjà?
24Ọ̀nà wo ni ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ń la, tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé?
25Ta ni ó la ipadò fún ẹ̀kún omi, àti ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,
26láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tí ènìyàn kò sí, ní aginjù níbi tí ènìyàn kò sí;
27láti mú ilẹ̀ tútù, ijù àti aláìro láti mú àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewéko rú jáde?
28Òjò ha ní baba bí? Tàbí ta ni o bí ìkún ìṣe ìrì?
29Láti inú ta ni ìdì omi ti jáde wá? Ta ni ó bí ìrì dídì ọ̀run?
30Nígbà tí omi di líle bí òkúta, nígbà tí ojú ibú ńlá sì dìpọ̀.
31“Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀ Pleiadesi dáradára? Tàbí ìwọ le tún di ìràwọ̀ Orioni?
32Ìwọ le mú àwọn àmì méjìlá ìràwọ̀ Masaroti jáde wá nígbà àkókò wọn? Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Beari pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀?
33Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run? Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé?
34“Ìwọ le gbé ohùn rẹ sókè dé àwọsánmọ̀ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kí ó lè bò ọ́?
35Ìwọ le rán mọ̀nàmọ́ná kí wọn kí ó le lọ, ní ọ̀nà wọn kí wọn kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Àwa nìyí’?
36Ta ni ó fi ọgbọ́n pamọ́ sí odò ikùn tàbí tí ó fi òye sínú àyà?
37Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọsánmọ̀? Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde,
38nígbà tí erùpẹ̀ di líle, àti ògúlùtu dìpọ̀?
39“Ìwọ ha dẹ ọdẹ fún abo kìnnìún bí? Ìwọ ó sì tẹ ebi ẹgbọrọ kìnnìún lọ́rùn,
40nígbà tí wọ́n bá mọ́lẹ̀ nínú ihò tí wọ́n sì ba ní ibùba de ohun ọdẹ?
41Ta ni ó ń pèsè ohun jíjẹ fún ẹyẹ ìwò, nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ń ké pe Ọlọ́run, tí wọ́n sì máa ń fò kiri nítorí àìní ohun jíjẹ?
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.