Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Jobu 3

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Ẹ̀yìn èyí ní Jobu yanu, ó sì fi ọjọ́ ìbí rẹ̀ ré
2Jobu sọ, ó sì wí pé,
3“Kí ọjọ́ tí a bí mi kí ó di ìgbàgbé, àti òru ni, nínú èyí tí a wí pé, ‘A lóyún ọmọkùnrin kan!’
4Kí ọjọ́ náà kí ó já si òkùnkùn, kí Ọlọ́run kí ó má ṣe kà á sí láti ọ̀run wá; bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ kí ó má ṣe mọ́ sí i.
5Kí òkùnkùn àti òjìji ikú fi ṣe ti ara wọn; kí àwọsánmọ̀ kí ó bà lé e; kí ìṣúdudu ọjọ́ kí ó pa láyà.
6Kí òkùnkùn kí ó ṣú bo òru náà biribiri, kí ó má ṣe yọ pẹ̀lú ọjọ́ ọdún náà: kí a má ṣe kà a mọ́ iye ọjọ́ oṣù.
7Kí òru náà kí ó yàgàn; kí ohun ayọ̀ kan kí ó má ṣe wọ inú rẹ̀ lọ.
8Kí àwọn tí í fi ọjọ́ gégùn ún kí o fi gégùn ún, tí wọ́n mura tán láti ru Lefitani sókè.
9Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ rẹ̀ kí ó ṣókùnkùn; kí ó má wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó máa mọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe rí àfẹ̀mọ́júmọ́
10nítorí tí kò sé ìlẹ̀kùn inú ìyá mi, láti pa ìbànújẹ́ rẹ́ ní ojú mi.
11“Èéṣe tí èmi kò fi kú láti inú wá, tàbí tí èmi kò kú ní ìgbà tí mo ti inú jáde wá?
12Èéṣe tí orúnkún wá pàdé mi, tàbí ọmú tí èmi yóò mu?
13Ǹjẹ́ nísinsin yìí èmi ìbá ti dùbúlẹ̀ jẹ́ẹ́; èmi ìbá ti sùn, èmi ìbá ti sinmi
14pẹ̀lú àwọn ọba àti ìgbìmọ̀ ayé tí wọ́n mọ ilé fún ara wọn wá dùbúlẹ̀ nínú ìsọdahoro.
15Tàbí pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé tí ó ní wúrà, tí wọ́n sì fi fàdákà kun ilé wọn.
16Tàbí bí ọlẹ̀ tí a sin, èmi kì bá ti sí: bí ọmọ ìṣunú tí kò rí ìmọ́lẹ̀?
17Níbẹ̀ ni ẹni búburú ṣíwọ́ ìyọnilẹ́nu, níbẹ̀ ni ẹni àárẹ̀ wà nínú ìsinmi.
18Níbẹ̀ ni àwọn ìgbèkùn sinmi pọ̀, wọn kò gbóhùn amúnisìn mọ́.
19Àti èwe àti àgbà wà níbẹ̀, ẹrú sì di òmìnira kúrò lọ́wọ́ olówó rẹ̀.
20“Nítorí kí ni a ṣe fi ìmọ́lẹ̀ fún òtòṣì, àti ìyè fún ọlọ́kàn kíkorò,
21tí wọ́n dúró de ikú, ṣùgbọ́n òun kò wá, tí wọ́n wá a jù ìṣúra tí a bò mọ́lẹ̀ pamọ́ lọ.
22Ẹni tí ó yọ̀ gidigidi, tí inú wọ́n sì dùn nígbà tí wọ́n wá ibojì òkú rí?
23Kí ni a fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ fi ara pamọ́ fún, tí Ọlọ́run sì ṣọgbà dí mọ́ ká?
24Nítorí pé èémí-ẹ̀dùn wà ṣáájú oúnjẹ mi; ìkérora mi sì tú jáde bí omi.
25Nítorí pé ohun náà tí mo bẹ̀rù gidigidi ni ó dé bá mi yìí, àti ohun tí mo fòyà rẹ̀ bá mi ó sì ṣubú lù mí.
26Èmi wà láìní àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ní ìsinmi; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ni ìfàyàbalẹ̀, bí kò ṣe ìdààmú.”
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.