Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Jobu 29

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Pẹ̀lúpẹ̀lú, Jobu sì tún tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé,
2“Háà! ìbá ṣe pé èmi wà bí ìgbà oṣù tí ó kọjá, bí ọjọ́ tí Ọlọ́run pa mí mọ́,
3nígbà tí fìtílà rẹ tàn sí mi ní orí, àti nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ èmi rìn nínú òkùnkùn já.
4Bí mo ti rí nígbà ọ̀dọ́ mi, nígbà tí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ bùkún ilé mi,
5nígbà tí Olódùmarè wà pẹ̀lú mi, nígbà tí àwọn ọmọ mi wà yí mi ká;
6nígbà tí èmi fi òrí-àmọ́ n wẹ ìṣísẹ̀ mi, àti tí àpáta ń tú ìṣàn òróró jáde fún mi wá.
7“Nígbà tí mo jáde la àárín ìlú lọ sí ẹnu ibodè, nígbà tí mo tẹ́ ìtẹ́ mi ní ìgboro,
8nígbà náà ni àwọn ọmọkùnrin rí mi, wọ́n sì sá pamọ́, àwọn àgbà dìde dúró ní ẹsẹ̀ wọn,
9àwọn ọmọ-aládé dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, wọn a sì fi ọwọ́ wọn lé ẹnu.
10Àwọn ọlọ́lá dákẹ́, ahọ́n wọn sì lẹ̀ mọ́ èrìgì ẹnu wọn.
11Nígbà tí etí gbọ́, ó sì súre fún mi, àti nígbà tí ojú sì rí mi, ó jẹ́rìí mi,
12nítorí mo gbà tálákà tí n fẹ́ ìrànlọ́wọ́, àti aláìní baba tí kò sí olùrànlọ́wọ́ fún un.
13Ẹni tí ó ń kìlọ̀ súre fún mi, èmi sì mú àyà opó kọrin fún ayọ̀.
14Èmi sì mú òdodo wọ̀ bí aṣọ, ẹ̀tọ́ mi dàbí aṣọ ìgúnwà àti adé ọba.
15Mo ṣe ojú fún afọ́jú mo sì ṣe ẹsẹ̀ fún amúnkùn ún.
16Mo ṣe baba fún tálákà; mo ṣe ìwádìí ọ̀ràn àjèjì tí èmi kò mọ̀ rí.
17Mo sì ká eyín ẹ̀rẹ̀kẹ́ ènìyàn búburú, mo sì já ohun ọdẹ náà kúrò ní eyín rẹ̀.
18“Nígbà náà ni mo rò pé, ‘Èmi yóò kú nínú ilé mi, èmi yóò sì mú ọjọ́ mi pọ̀ sí i bí iyanrìn.
19Gbòǹgbò mi yóò ta kan omi, ìrì yóò sì sẹ̀ ní gbogbo òru sí ara ẹ̀ka mi.
20Ògo mi yóò wà ní ọ̀tún ní ọ̀dọ̀ mi, ọrun mi sì padà di tuntun ní ọwọ́ mi.’
21“Èmi ni ènìyàn ń dẹtí sílẹ̀ sí, wọn a sì dúró, wọn a sì dákẹ́ rọ́rọ́ ní ìmọ̀ràn mi.
22Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ mi, wọn kò tún sọ̀rọ̀ mọ́; ọ̀rọ̀ mi wọ̀ wọ́n ní etí ṣinṣin.
23Wọn a sì dúró dè mí bí ẹni wí pé wọ́n dúró fún ọ̀wọ́ òjò; wọn a sì mu nínú ọ̀rọ̀ mi bí ẹní mu nínú òjò àrọ̀kúrò.
24Èmi sì rẹ́rìn-ín sí wọn nígbà tí wọn kò bá gbà á gbọ́; ìmọ́lẹ̀ ojú mi jẹ́ iyebíye sí wọn.
25Mo la ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn, mo sì jókòó bí olóyè wọn. Mo jókòó bí ọba ní àárín ológun rẹ, mo sì rí bí ẹni tí ń tu ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.