Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Jobu 17

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1“Ẹ̀mí mi bàjẹ́, ọjọ́ mi ni a ti gé kúrú, isà òkú dúró dè mí.
2Nítòótọ́ àwọn ẹlẹ́yà wà lọ́dọ̀ mi, ojú mi sì tẹ̀mọ́ ìmúnibínú wọn.
3“Fi fún mi Olúwa, ìlérí tí ìwọ fẹ́; ta ni yóò le ṣe ààbò fún mi?
4Nítorí pé ìwọ ti sé wọ́n láyà kúrò nínú òye; nítorí náà ìwọ kì yóò gbé wọn lékè.
5Ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn dídún fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún èrè, òun ni ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú òfo.
6“Ọlọ́run ti sọ mi di ẹni òwe fún àwọn ènìyàn; níwájú wọn ni mo dàbí ẹni ìtutọ́ sí ní ojú.
7Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́, gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji.
8Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí, ẹni aláìṣẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè.
9Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú, àti ọlọ́wọ́ mímọ́ yóò máa lera síwájú.
10“Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín, ẹ yípadà, kí ẹ si tún padà nísinsin yìí; èmi kò le rí ọlọ́gbọ́n kan nínú yín.
11Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìrò mi ti fà yá, àní ìrò ọkàn mi.
12Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń ṣọ́ òru di ọ̀sán; wọ́n ní, ìmọ́lẹ̀ súnmọ́ ibi tí òkùnkùn dé.
13Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilé mi; mo ti tẹ́ ibùsùn mi sínú òkùnkùn.
14Èmi ti wí fún ìdíbàjẹ́ pé, ìwọ ni baba mi, àti fún kòkòrò pé, ìwọ ni ìyá mi àti arábìnrin mi,
15ìrètí mi ha dà nísinsin yìí? Bí ó ṣe ti ìrètí mi ni, ta ni yóò rí i?
16Yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ipò òkú, nígbà tí a jùmọ̀ sinmi pọ̀ nínú erùpẹ̀ ilẹ̀?”
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.