Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Jobu 11

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Ìgbà náà ni Sofari, ará Naama, dáhùn, ó sì wí pé,
2“A ha lè ṣe kí a máa dáhùn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀? A ha lè fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí da ènìyàn láre?
3Ṣé àmọ̀tán rẹ le mú ènìyàn pa ẹnu wọn mọ́ bí? Ṣé ẹnikẹ́ni kò ní bá ọ wí bí ìwọ bá yọ ṣùtì sí ni?
4Ìwọ sá à ti wí fún Ọlọ́run pé, ‘Ìṣe mi jẹ́ aláìléérí, èmi sì mọ́ ní ojú rẹ.’
5Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ìbá jẹ́ sọ̀rọ̀, kí ó sì ya ẹnu rẹ̀ sí ọ
6kí ó sì fi àṣírí ọgbọ́n hàn ọ́ pé, ó pọ̀ ju òye ènìyàn lọ, nítorí náà, mọ̀ pé Ọlọ́run ti gbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kan.
7“Ìwọ ha le ṣe àwárí ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí? Ìwọ ha le ṣe àwárí ibi tí Olódùmarè dé bi?
8Ó ga ju àwọn ọ̀run lọ; kí ni ìwọ le è ṣe? Ó jìn ju jíjìn isà òkú lọ; kí ni ìwọ le mọ̀?
9Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ayé lọ, ó sì ní ibú ju òkun lọ.
10“Bí òun bá rékọjá, tí ó sì sé ọnà tàbí tí ó sì mú ni wá sí ìdájọ́, ǹjẹ́, ta ni ó lè dí i lọ́wọ́?
11Òun sá à mọ ẹlẹ́tàn ènìyàn; àti pé ṣé bí òun bá rí ohun búburú, ṣé òun kì i fi iyè sí i?
12Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn ki yóò di ọlọ́gbọ́n bi ko ti rọrùn fún ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó láti bí ènìyàn.
13“Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un, tí ìwọ sì na ọwọ́ rẹ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,
14bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù tí ìwọ kò sì jẹ́ kí aburú gbé nínú àgọ́ rẹ,
15nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láìní àbàwọ́n, àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù.
16Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ; ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti sàn kọjá lọ.
17Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ, bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísinsin yìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀.
18Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà; àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.
19Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́, àní ènìyàn yóò máa wá ojúrere rẹ.
20Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo; gbogbo ọ̀nà àbáyọ ni yóò nù wọ́n, ìrètí wọn a sì dàbí ẹni tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.”
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.