Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Isaiah 4

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Ní ọjọ́ náà, obìnrin méje yóò dì mọ́ ọkùnrin kan yóò sì wí pé, “Àwa ó máa jẹ oúnjẹ ara wa a ó sì pèsè aṣọ ara wa; sá à jẹ́ kí a máa fi orúkọ rẹ̀ pè wá. Mú ẹ̀gàn wa kúrò!” Ẹ̀ka Olúwa náà
2Ní ọjọ́ náà, ẹ̀ka Olúwa yóò ní ẹwà àti ògo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ìgbéraga àti ògo àwọn ti ó sálà ní Israẹli.
3Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Sioni, àwọn tí o kù ní Jerusalẹmu, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní Jerusalẹmu.
4Olúwa yóò wẹ ẹ̀gbin àwọn obìnrin Sioni kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí iná.
5Lẹ́yìn náà, Olúwa yóò dá sórí òkè Sioni àti sórí i gbogbo àwọn tí ó péjọpọ̀ síbẹ̀, kurukuru èéfín ní ọ̀sán àti ìtànṣán ọ̀wọ́-iná ní òru, lórí gbogbo ògo yìí ni ààbò yóò wà.
6Èyí ni yóò jẹ́ ààbò àti òjìji kúrò lọ́wọ́ ooru ọ̀sán, àti ààbò òun ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì àti òjò.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.