Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Isaiah 17

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Damasku: “Kíyèsi i, Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́ ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn.
2Àwọn ìlú Aroeri ni a ó kọ̀sílẹ̀ fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn síbẹ̀, láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.
3Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Efraimu, àti agbára ọba kúrò ní Damasku; àwọn àṣẹ́kù Aramu yóò dá gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Israẹli,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
4“Ní ọjọ́ náà ni ògo Jakọbu yóò sá; ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù.
5Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkórè kó àwọn irúgbìn tí ó dúró jọ tí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀— àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní àfonífojì ti Refaimu.
6Síbẹ̀síbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi olifi, tí èso olifi méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kù sórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ, mẹ́rin tàbí márùn-ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,” ni Olúwa wí, àní Ọlọ́run Israẹli.
7Ní ọjọ́ náà, àwọn ènìyàn yóò gbójú sókè sí Ẹlẹ́dàá wọn, wọn yóò sì síjú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli.
8Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́, èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn, wọn kò sì ní kọbi ara sí ère Aṣerah mọ́ tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe.
9Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára rẹ̀, yóò dàbí ẹ̀ka ìkọ̀sílẹ̀, àti ẹ̀ka téńté òkè tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.
10Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ; tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀.
11Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àṣàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hù jáde, àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n ẹ mú kí wọ́n rúdí, síbẹ̀síbẹ̀ ìkórè kò ní mú nǹkan wá ní ọjọ́ ààrùn àti ìrora tí kò gbóògùn.
12Kíyèsi i, ìrunú àwọn orílẹ̀-èdè— wọ́n ń runú bí ìgbì Òkun! Kíyèsi i, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn wọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá!
13Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò, nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n sálọ jìnnà réré, a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè, àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.
14Ní aginjù, ìpayà òjijì! Kí ó tó di òwúrọ̀, a ò rí wọn mọ́! Èyí ni ìpín àwọn tí ó jí wa lẹ́rù, àti ìpín àwọn tí ó fi ogun kó wa.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.