Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Isaiah 12

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé, “Èmi ó yìn ọ́, Olúwa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀ ìwọ sì ti tù mí nínú.
2Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi, èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù. Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi, òun ti di ìgbàlà mi.”
3Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi láti inú kànga ìgbàlà.
4Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé, “Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ti ṣe kí o sì kéde pé a ti gbé orúkọ rẹ̀ ga.
5Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo, jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.
6Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni, nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo ti Israẹli láàrín yín.”
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.