Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

Hosea 4

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé Olúwa fi ẹ̀sùn kan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà. “Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́, Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà,
2àfi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn olè jíjà àti panṣágà. Wọ́n rú gbogbo òfin, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀.
3Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù. Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹja inú omi ló ń kú.
4“Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá, kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹnìkejì nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbí àwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà.
5Ẹ ń ṣubú lọ́sàn án àti lóru àwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lú yín. Èmi ó pa ìyá rẹ run,
6àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀. “Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀. Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi; nítorí pé ẹ ti kọ òfin Ọlọ́run yín sílẹ̀, Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín.
7Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí i bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi. Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú
8wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi, wọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn.
9Yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe rí náà ni àwọn àlùfáà rí. Èmi ó jẹ gbogbo wọn ní yà nítorí ọ̀nà wọn. Èmi ó sì san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.
10“Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó; wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i, nítorí pé wọ́n ti kọ Olúwa sílẹ̀, wọ́n sì ti fi ara wọn
11fún àgbèrè; wọ́n fi ara wọn fún wáìnì àtijọ́, àti tuntun èyí tó gba òye àwọn ènìyàn mi sọnù.
12Wọ́n ń gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ère igi ọ̀pá igi sì ń dá wọn lóhùn. Ẹ̀mí àgbèrè ti mú wọn ṣìnà wọ́n sì jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wọn.
13Wọ́n ń rú ẹbọ lórí àwọn òkè ńlá, wọ́n sì ń sun ọrẹ tùràrí lórí àwọn òkè kékeré, lábẹ́ igi óákù, àti igi Poplari àti igi ẹlimuati onírúurú igi tí ìbòjú rẹ̀ dára. Nítorí náà àwọn ọmọbìnrin yín yóò ṣe àgbèrè àti àwọn àfẹ́sọ́nà yín yóò ṣe àgbèrè.
14“Èmi kò ní jẹ àwọn ọmọbìnrin yín ní yà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè tàbí àwọn àfẹ́sọ́nà ọmọ yín, nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè nítorí pé àwọn ọkùnrin pàápàá ń bá alágbèrè kẹ́gbẹ́. Wọ́n sì ń rú ẹbọ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ojúbọ òrìṣà. Nítorí náà, ènìyàn tí kò bá ní òye yóò parun!
15“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Israẹli, ìdájọ́ yìí wà fún un yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí Juda di ẹlẹ́bi. “Ẹ má ṣe lọ sí Gilgali. Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Beti-Afeni ẹ má sì búra pé, ‘Bí Olúwa ti wà láààyè nítòótọ́!’
16Àwọn ọmọ Israẹli ṣe agídí bí alágídí ọmọ màlúù. Báwo wá ni Olúwa ṣe fẹ́ bọ́ wọn bí àgùntàn ní pápá oko tútù?
17Efraimu ti darapọ̀ mọ́ òrìṣà, ẹ fi sílẹ̀!
18Bí ohun mímu wọn bá tilẹ̀ tán, wọ́n tún tẹ̀síwájú nínú àgbèrè. Àwọn olórí wọn fẹ́ràn ohun ìtìjú ju ohun ìyìn lọ.
19Ìjì ni yóò gbá wọn lọ. Gbogbo ìrúbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.