Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

1 Kronika 8

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Benjamini jẹ́ baba: Bela àkọ́bí rẹ̀, Aṣbeli ọmọkùnrin ni ẹ̀ẹ̀kejì, Ahara ẹ̀ẹ̀kẹ́ta,
2Noha ẹ̀ẹ̀kẹrin àti Rafa ẹ̀karùnún.
3Àwọn ọmọ Bela ni, Adari, Gera, Abihudi,
4Abiṣua, Naamani, Ahoa,
5Gera, Ṣefufani àti Huramu.
6Wọ̀nyí ni àwọn ìran ọmọ Ehudu, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé tí ó ń gbé ní Geba tí a sì lé kúrò lọ sí Manahati:
7Naamani Ahijah àti Gera, tí ó lé wọn kúrò ní ìlú, àti tí ó sì jẹ́ baba Ussa àti Ahihudu.
8A bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣaharaimu ní Moabu lẹ́yìn tí ó ti kọ àwọn ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, Huṣimu àti Baara.
9Nípasẹ̀ ìyàwó rẹ̀ Hodeṣi ó ní Jobabu Sibia, Meṣa, Malkamu,
10Jeusi, Sakia àti Mirma. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, olórí àwọn ìdílé.
11Nípasẹ̀ Huṣimu ó ní Abitubu àti Elipali.
12Àwọn ọmọ Elipali: Eberi, Miṣamu, Ṣemedu (ẹni tí ó kọ́ Ono àti Lodi pẹ̀lú àwọn ìletò àyíká rẹ̀.)
13Pẹ̀lú Beriah àti Ṣema, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé ti àwọn tí ó ń gbé ní Aijaloni àti àwọn tí ó lé àwọn olùgbé Gati kúrò.
14Ahio, Ṣasaki, Jeremoti,
15Sebadiah, Aradi, Ederi
16Mikaeli, Iṣifa àti Joha jẹ́ àwọn ọmọ Beriah.
17Sebadiah, Meṣullamu, Hiski, Heberi
18Iṣimerai, Isiliahi àti Jobabu jẹ́ àwọn ọmọ Elipali.
19Jakimu, Sikri, Sabdi,
20Elienai, Siletai, Elieli,
21Adaiah, Beraiah àti Ṣimrati jẹ́ àwọn ọmọ, Ṣimei.
22Iṣipani Eberi, Elieli,
23Abdoni, Sikri, Hanani,
24Hananiah, Elamu, Anitotijah,
25Ifediah àti Penueli jẹ́ àwọn ọmọ Ṣasaki.
26Ṣamṣerai, Ṣeharaiah, Ataliah
27Jareṣiah, Elijah àti Sikri jẹ́ àwọn ọmọ Jerohamu.
28Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn ìdílé, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìran wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu.
29Jeieli, baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni. Ìyàwó o rẹ̀ a má jẹ́ Maaka,
30àkọ́bí rẹ̀ a sì máa jẹ́ Abdoni wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu,
31Gedori Ahio, Sekeri
32pẹ̀lú Mikiloti, tí ó jẹ́ baba Ṣimea. Wọ́n ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu.
33Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba Saulu àti Saulu baba Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali.
34Ọmọ Jonatani: Meribu-Baali tí ó jẹ́ baba Mika.
35Àwọn ọmọ Mika: Pitoni, Meleki, Tarea, àti Ahasi.
36Ahasi jẹ́ baba a Jeheada, Jeheada jẹ́ baba a Alemeti, Asmafeti àti Simri, Simri sì jẹ́ baba Mosa.
37Mosa jẹ́ baba Binea; Rafa sì jẹ́ ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀ àti Aseli ọmọ rẹ̀.
38Aseli ní ọmọ mẹ́fà pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn: Asrikamu, Bokeru, Iṣmaeli, Ṣeariah, Obadiah àti Hanani. Gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Aseli.
39Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Eseki: Ulamu àkọ́bí rẹ̀, Jeuṣi ọmọkùnrin ẹ̀ẹ̀kejì àti Elifeleti ẹ̀ẹ̀kẹ́ta.
40Àwọn ọmọ Ulamu jẹ́ ògboyà jagunjagun tí ó lè gbá orin mú. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin àti ọmọ ọmọkùnrin áàdọ́jọ ní gbogbo rẹ̀. Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ìran ọmọ Benjamini.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.