Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (2017)

1 Kronika 3

Ka Bíbélì ní èdè Yorùbá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.

1Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Hebroni. Àkọ́bí sì ni Amnoni ọmọ Ahinoamu ti Jesreeli; èkejì sì ni Daniẹli ọmọ Abigaili ará Karmeli;
2ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un; ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti;
3ẹ̀karùnún ni Ṣefatia láti ọ̀dọ̀ Abitali; àti ẹ̀kẹfà, Itreamu, láti ọ̀dọ̀ Egla aya rẹ̀.
4Àwọn mẹ́fà wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà. Dafidi sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n.
5Wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un ní Jerusalẹmu: Ṣimea, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bati-Ṣua ọmọbìnrin Ammieli.
6Ibhari sì wà pẹ̀lú, Eliṣama, Elifeleti,
7Noga, Nefegi, Jafia,
8Eliṣama, Eliada àti Elifeleti mẹ́sàn-án ni wọ́n.
9Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dafidi yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un. Tamari sì ni arábìnrin wọn.
10Ọmọ Solomoni ni Rehoboamu, Abijah ọmọ rẹ̀, Asa ọmọ rẹ̀, Jehoṣafati ọmọ rẹ̀,
11Jehoramu ọmọ rẹ̀, Ahasiah ọmọ rẹ̀, Joaṣi ọmọ rẹ̀,
12Amasiah ọmọ rẹ̀, Asariah ọmọ rẹ̀, Jotamu ọmọ rẹ̀,
13Ahasi ọmọ rẹ̀, Hesekiah ọmọ rẹ̀, Manase ọmọ rẹ̀,
14Amoni ọmọ rẹ̀, Josiah ọmọ rẹ̀.
15Àwọn ọmọ Josiah: àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni Johanani, èkejì ọmọ rẹ̀ ni Jehoiakimu, ẹ̀kẹta ọmọ rẹ̀ ni Sedekiah, ẹ̀kẹrin ọmọ rẹ̀ ni Ṣallumu.
16Àwọn ìran ọmọ Jehoiakimu: Jekoniah ọmọ rẹ̀, àti Sedekiah.
17Àwọn ọmọ Jekoniah tí a mú ní ìgbèkùn: Ṣealitieli ọmọ rẹ̀ ọkùnrin,
18Malkiramu, Pedaiah, Ṣenasari, Jekamiah, Hoṣama àti Nedabiah.
19Àwọn ọmọ Pedaiah: Serubbabeli àti Ṣimei. Àwọn ọmọ Serubbabeli: Meṣullamu àti Hananiah. Ṣelomiti ni arábìnrin wọn.
20Àwọn márùn-ún mìíràn sì tún wà: Haṣuba, Oheli, Berekiah, Hasadiah àti Jusabhesedi.
21Àwọn ọmọ Hananiah: Pelatiah àti Jeṣaiah, àti àwọn ọmọ Refaiah, ti Arnani, ti Obadiah àti ti Ṣekaniah.
22Àwọn ọmọ Ṣekaniah: Ṣemaiah àti àwọn ọmọ rẹ̀: Hattusi, Igali, Bariah, Neariah àti Ṣafati, mẹ́fà ni gbogbo wọn.
23Àwọn ọmọ Neariah: Elioenai; Hesekiah, àti Asrikamu, mẹ́ta ni gbogbo wọn.
24Àwọn ọmọ Elioenai: Hodafiah, Eliaṣibu, Pelaiah, Akkubu, Johanani, Delaiah àti Anani, méje sì ni gbogbo wọn.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ — Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 Biblica, Inc. Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ — Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission in the original work. Original work by Biblica, Inc. is freely available at biblica.com and open.bible. Digital source: eBible.org/yor. License: Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 (CC BY-SA 4.0). Changes to presentation: Bible verse-only formatting, removal of source headings, navigation and footnotes, and flattening of HTML layout; Scripture wording is unchanged. This adapted Scripture presentation remains available under CC BY-SA 4.0. Biblica® trademarks are cited solely to identify the original edition, not as Divine Threads branding, and Biblica does not endorse this site. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Divine Threads ní Yorùbá ń bọ̀ láìpẹ́.